Hymn 495: Shall we gather at the river

A o pade leti odo

  1. mf A o pade leti odo,
    T’ ẹsẹ angẹli ti tẹ̀,
    T’o mọ́ gara bi kristali,
    Lẹba itẹ Ọlọrubn?
    f A o pade leti odò,
    Odò didan, odò didan na,
    Pẹl’ awọn mimọ́ lẹba odò,
    T’o nṣàn lẹba itẹ́ nì.

  2. mf Leti bebe odò na yi,
    Pẹl’ Oluṣagutan wa,
    A o ma rìn, a o ma sìn,
    B’a ti ntẹle ‘pasẹ Rẹ̀.
    f A o pade leti odò, &c.

  3. p K’ a to de odo didan na,
    A o s’ẹrù wa kalẹ̀;
    cr Jesu, jọ gba ẹrù ẹ̀ṣẹ
    Awọn ti O de l’ade.
    f A o pade leti odò, &c.

  4. cr Njẹ l’ẹba odo tutu na,
    Ao r’oju Olugbala;
    Ẹmi wa kì o pinya mọ,
    Yio kọrin ogo Rẹ̀.
    f A o pade leti odò, &c. Amin.