Hymn 494: One there is above all others

Enikan mbe t’ O feran wa

  1. mf Ẹnikan mbẹ t’O fẹràn wa,
    A ! O fẹ wa !
    Ifẹ Rẹ̀ ju ti yèkan lọ,
    A ! O fẹ wa !
    p Ọrẹ́ aiye nkọ̀ wa silẹè,
    B’oni dùn ọla lè korò,
    cr Ṣugbọn ọrẹ́ yi kò ntanni,
    A ! O fẹ wa !

  2. mf Iyè ni fun wa b’ a ba mọ,
    A ! O fẹ wa !
    di Rò b’ a ti jẹ ni gbesè to,
    A ! O fẹ wa !
    p Ẹjẹ Rẹ̀ l’O sì fi rà wa,
    Nin’ agbanju l’O wá wa ri,
    cr O sì mu wa wá s’ agbo Rẹ̀,
    A ! O fẹ wa !

  3. f Ọrẹ́ ododo ni Jesu,
    A ! O fẹ wa !
    O fẹ lati ma bukun wa,
    A ! O fẹ wa !
    Ọkàn wa fẹ gbó ohun Rẹ̀,
    Ọkàn wa fẹ lati sunmọ,
    On na kò si ni tàn wa je.
    A ! O fẹ wa !

  4. p Lokọ Rẹ̀ l’a nri ‘dariji,
    A ! O fẹ wa !
    cr On O le ọ̀ta wa sẹhin,
    A ! O fẹ wa !
    f On O pesè ‘bukun fun wa;
    Ire l’a O ma ri titi
    ff On O fi mu wa lọ s’ogo.
    A ! O fẹ wa ! Amin.