- f Hosanna ! ẹ korin sokè,
S’ ọmọ nla Dafidi;
Pẹlu Kẹrub ati Seraf
K’ a yin Ọm’ Ọlọrun.
- mp Hosanna ! eyi na nikan,
L’ ahọn wa le ma kọ;
cr Iwọ kì o kẹgàn ewe,
Ti nkọrin ìyin Rẹ.
- f Hosanna ! Alufa, Ọba,
Ẹbun Rẹ ti pọ̀ to !
Ẹjẹ Rẹ l’ o jẹ ìye wa,
Ọrọ Rẹ ni onjẹ.
- mf Hosanna ! Baba, awa mu
Ọrẹ wa wá fun Ọ,
Ki ṣe wura on ojia,
Bikoṣe ọkàn wa.
- Hosanna ! Jesu, lẹkan ri,
O yìn awọn ewe;
cr Ṣanu fun wa, si f’eti si
Orin awa ewe.
- mf Jesu, b’ o ba rà wa paa,
T’ a si wọ̀ jọba Rẹ;
A o fi harpu wura kọ
Hosanna titi lai. Amin.