- mf Oluṣagutan mi,
Ma bọ́ mi titi;
Oluṣagutan mi,
Ma tọ́ ẹsẹ mi.
- Di mi mu, si tọ́ mi,
Ni ọnà hiha;
B’ O ba wà lọdọ mi,
Emi kò sina.
- Sìn mi s’ ọna ọrun,
Ni ojojumọ;
Ma busi ‘gbagbọ mi,
Si mu mi fẹ Ọ.
- K’ ayọ̀ tabi ẹkun,
Ti ọdọ Rẹ wá;
K’ ìye ainipẹkun,
Lè jẹ ayọ̀ mi.
- Ma pesè ọkàn mi,
Ni ojojumọ;
Si jẹ k’ Angẹli Rẹ,
Sìn mi lọ ile. Amin.