- mf Máṣe huwa ẹ̀ṣẹ,
Má sọ̀rọ ‘binu;
Ọmọ Jesu l’ ẹ ṣe,
Ọmọ Oluwa.
- mf Krist jẹ oninure,
At’ ẹni mimọ́;
Bẹ l’ awọn ọmọ Rè
Yẹ k’o jẹ mimọ́.
- p Ẹmi ibi kan wà,
T’ o nṣọ ìrin rẹ;
O si nfẹ dan ọ wò,
Lati ṣe ibi.
- Ẹ má ṣe gbọ́ tirẹ̀.
B’ o tilẹ̀ ṣoro
Lati ba Eṣu jà,
Lati ṣe rere.
- mf Ẹnyin ti ṣe ‘leri
Ni ọmọ-ọwọ,
Lati k’ Eṣu silẹ,
Ati ọ̀na rẹ̀.
- Ọm’ ogun Krist ni nyin,
Ẹ kọ́ lati bá
Ẹṣẹ inu nyin jà;
Ẹ ma ṣe rere.
- f Jesu l’Oluwa nyin,
cr O ṣe ẹnire;
Ki ẹnyin ọmọ Rẹ̀
Si ma ṣe rere. Amin.