- f Jesu, a w’ ọdọ Rẹ,
L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yì;
Tọ̀ wa wá b’ awa ti pejọ,
Si kọ́ wa fun ‘ra Rẹ.
- p Dari ẹ̀ṣẹ jì wa,
Fun wa l‘ Ẹmi Mimọ́;
Kọ wa k’ ihin jẹ ìbẹrẹ
Aiye ti kò l’ opin.
- f F’ ifẹ kun aiya wa,
Gba ‘ṣẹ́ olukọ́ wa;
K’ awa at’ awọn lè pade
Niwaju Rẹ loke. Amin.