- Ọsẹ, Ọsẹ rere,
Iwọ ọjọ simi;
O yẹ k’ a fi ọjọ kan,
Fun Ọlọrun rere;
B’ ọjọ mi ba m’ ẹkùn wa,
Iwọ n’ oju wa nù;
Iwọ ti ṣ’ ọjọ ayọ̀,
Emi fẹ dide rẹ.
- Ọsẹ, Ọsẹ rere,
A ki o ṣiṣẹ loni;
A o f’ iṣẹ wa gbogbo
Fun aisimi ọla.
Didan l’oju rẹ ma dán,
‘Wọ arẹwà ọjọ;
Ọjọ mi nsọ ti lala,
Iwọ nsọ ti ‘simi.
- Ọsẹ, Ọsẹ rere,
Ago tilẹ nwipe,
F’ Ẹlẹda rẹ l’ ọjọ kan,
T’O fun ọ n’ijọ mẹfa:
A o ti ‘ṣẹ wa silẹ,
Lati lọ sin nibẹ,
Awa ati ọrẹ wa,
Ao lọ sile adua.
- Ọsẹ, Ọsẹ rere,
Wakati rẹ wù mi;
Ọjọ ọrun ni ‘wọ ṣe,
‘Wọ apẹrẹ ọrun;
Oluwa, jẹ ki njogun
Simi lẹhin ikú;
Ki nlè ma sin Ọ titi,
Pẹlu enia Rẹ. Amin.