Hymn 487: I Cherished Thee My Sunday School

Ile- eko ojo ’simi

  1. Ile-ẹkọ ọjọ ‘simi,
    A, mo ti fẹ ọ to !
    Inu mi dùn mo daraya,
    Lati yọ̀ ayọ̀ rẹ.

  2. Ile-ẹkọ ọjọ ‘simi,
    Ọrẹ́ rẹ p’ àpọju;
    T’ agba t’ ewe wa nkọrin rẹ,
    A nṣe afẹri rẹ.

  3. Ile-ẹkọ ọjọ ‘simi,
    Jesu l’o ti kọ́ ọ;
    Ẹmi Mimọ Olukọni,
    L’o sì nṣe ‘tọju rẹ.

  4. Ile-ẹkọ ọjọ ‘simi,
    Awa ri ẹri gbà,
    P’ Ọlọrun Olodumare
    F’ ibukun sori rẹ.

  5. Ile-ẹkọ ọjọ ‘simi,
    B’orùn nràn l’àrànjù,
    Bi ojo ṣú dùdu lọrun,
    Ninu rẹ̀ l’emi o wá.

  6. Ile-ẹkọ ọjọ ‘simi,
    Mo yọ̀ lati ri Ọ,
    ‘Wọ y’o ha kọja lori mi
    Loni, l’ airi ‘bukun ? Amin.