- p Ọj’ oni lọ,
Jesu Baba,
Boju Rẹ w’ẹ̀mi ọmọ Rẹ.
- ‘Wọ Imọlẹ,
Ṣe ‘tọju mi;
Tàn imọlẹ Rẹ yi mi ka.
- Olugbala,
Nko ni bẹ̀ru,
Nitori O wà lọdọ mi.
- Nigba gbogbo
Ni oju Rẹ
Nṣọ mi, gbat’ ẹnikan kò si.
- Nigba gbogbo
Ni eti Rẹ
Nṣi si adurà ọmọde.
- Nitorina
Laisi foyà,
Mo sùn, mo is simi le Ọ.
- Baba, Ọmọ,
Ẹmi Mimọ́
Ni iyìn yẹ l’ ọrun l’ aiye. Amin.