mp Nihin l’ awa nje ‘rora, Nihin ni a ma pinya; mf L’ọrun, kò si ‘pinya, f A ! bi o ti dùn to! Dùn to, dùn to, dùn to! A ! bi o ti dùn to! ‘Gba t’ a kì o pinya mọ !
mf Awọn t’ o fẹràn Jesu, Nwọn o lọ s’ oke ọrun, Lọ b’ awọn t’o ti lọ, f A ! bi o ti dùn to ! &c.
mf Ọmọde y’o wà nibẹ̀, T’o wá Ọlọrun l’aiye; Ni gbogbo ‘le ẹ̀kọ; f A ! bi o ti dùn to ! &c.
Olukọ, baba, ìya, Nwọn o pade nibẹ̀ na; Nwọn ki o pinya mọ. f A ! bi o ti dùn to ! &c.
ff Bi a o ti yọ̀ pọ̀ to ! ‘Gba t’a ba r’ Olugbala, Ni ori itẹ Rẹ̀ ! A ! bi o ti dùn to ! &c.
Nibẹ̀ l’ao kọrin ayọ̀; Titi aiye ailopin, L’ a o ma yìn Jesu A ! bi o ti dùn to! Dùn to, dùn to, dùn to! A ! bi o ti dùn to! ‘Gba t’ a kì o pinya mọ ! Amin.