- mf Ọmọde, ẹ sunm’ Ọlọrun,
p Pẹlu irẹlẹ̀ at’ ẹ̀ru;
Ki ekun gbogbo wolẹ̀ fun
Olugbala at’Ọrẹ́ wa.
- mf Oluwa, jẹ k’ anu Rẹ nla,
Mu wa kun fun ọpẹ si Ọ;
Ati b’ a ti nrin lọ l’ aiye,
K’ a ma ri ọpọ anu gbà.
- Oluwa! m’erò buburu,
Jinna réré si ọkàn wa;
L’ ojojumọ fun wa l’ọgbọ́n,
Lati yan ọnà toro nì.
- p Igba aisàn, at’ ilera
Igba aini tabi ọrọ̀;
pp Ati l’akoko ikú wa,
f Fi agbara Tirẹ gbà wa. Amin.