- ‘Gba Jesu f’itẹ̀ Rẹ̀ silẹ̀,
p O mu ‘pò irẹlẹ̀;
Ni ‘rẹlẹ̀ o mu awọ̀ wa,
pp O wa gbé ‘nu aiye.
- A ba lè rìn bi On ti rìn,
Nipa ọnà ọgbọ́n;
K’ a dagba l’ore at’ ọgbọ́n,
Bi ọdun ti npọ̀ si.
- Didun l’ọ̀rọ, at’ ìwo Rẹ̀;
Gb’ awọn iyá sunmọ;
O gb ọmọ wọn s’ apa Rẹ̀,
O si sure fun wọn.
- Labẹ itọju Rẹ̀, nwọn bó
Lọwọ ‘tanjẹ aiye;
Bayi ni k’awa dubulẹ̀,
Ni iṣọ oju Rẹ̀.
- Gba Jesu gun kẹtẹkẹtẹ,
Awọn ‘mọde nkọrin;
f L’ ayọ̀ nwọn ke ẹka igi,
Nwọn si tẹ ‘ṣọ silẹ.
- B’ awa gbagbe ìyin Jesu,
Okuta y’o kọrin !
ff Hosanna ni awa o kọ,
cr Hosanna s’Ọba wa. Amin.