- f Gbọ ‘gb ayọ! Oluwa de,
Jesu t’a ṣèleri;
Ki gbogbo ọkàn mura de,
K’ ohùn mura kọrin.
- O de lati t’ondè silẹ
L’ oko ẹru Eṣu;
ff ‘Lẹkùn ‘de fọ niwaju Rè.
Ṣẹkẹṣẹkẹ ‘rin dá.
- mf O de larin ‘bajẹ aiye
Lati tàn ‘mọlẹ Rè,
Lati mu k’awọn afọju
Le f’oju wọn riran.
- p O de, ‘tunu f’ọkàn ‘rora,
Iwòsan f’agbọgbe;
cr Pẹlu ‘ṣura or’ọfẹ Rè
Fun awọn talaka.
- un Hosanna, Ọba ‘lafia,
Ao kede bibọ Rẹ:
Gbogbo ọrun y’o ma kọrin
Orukọ t’a fẹràn. Amin.