- f Yikà or’ itẹ Ọlọrun,
Ẹgbẹrun ewe wà;
Ewe t’ a dari ẹ̀ṣẹ ji,
Awọn ẹgbẹ mimọ́:
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
- Wo ! olukuluku wọn wọ̀
Aṣọ àla mimọ;
Ninu imọlẹ ailopin,
At’ ayọ̀ ti ki ṣá,
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
- mf Kil’ o mu wọn de aiye na,
Ọrun t’o ṣe mimọ́,
cr Nib’ alafia at’ ayọ̀,
Bi nwọn ti ṣe de ‘bẹ̀?
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
- p Nitori Jesu ta ‘jẹ Rẹ̀,
Lati k’ẹṣẹ wọn lọ;
A rì wọn ninu ẹjẹ na,
Nwọn di mimọ́ laulau;
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
- mf L’ aiye, nwọn wá Olugbala,
Nwọn fẹ orukọ Rẹ̀’
cr Nisisiyi nwọn r’ oju Rẹ̀,
Nwọn wà niwaju Rẹ̀;
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
- p Orisun na ha nṣàn loni?
Jesu, mu wa de ‘bẹ̀;
K’a le ri awọn mimọ́ na,
cr K’ a si ba wọn yìn Ọ,
f Nkọrin Ogo, ogo, ogo. Amin.