- mf Ọna kan l’o ntọka sọrun,
Iṣina ni ‘yoku;
Hiha si l’oju ọ̀na na,
Awọn Kristian l’o fẹ.
- Lat’ aiye, o lọ tàrata,
O sì la ewu lọ;
cr Awọn ti nf’ igboyà rìn i,
Y’o d’ọrun nikẹhìn.
- mf Awọn ewe y’o ha ti ṣe
Le là ewu yi ja?
‘Tori idẹ̀kùn pọ̀ lọnà
F’ awọn ọdọmọde !
- p Gbigboro lọna t’ọ̀pọ nrìn,
O sì tẹju pẹlu !
Mo sì mọ pe lati dẹṣẹ
Ni nwọn ṣe nrìn nibẹ.
- mf Ṣugbọn k’ẹsẹ mi ma bà yẹ̀,
Ki nmá sì ṣako lọ,
Oluwa, jọ ṣ’olutọ mi,
Emi ki o ṣina.
- Njẹ mo le lọ l’ ais’ ifoya,
Ki ngbẹkẹl’ ọrọ Rẹ̀;
p Apa Rẹ̀ y’o ṣ’ agutan Rẹ̀,
Y’o sì ko wọn de ‘le.
- cr Bẹni ngo là ewu yi ja
Nipa itọju Rẹ̀;
f Ngo tẹjumọ ‘bode ọrun
Titi ngo fi wọle. Amin.