- Ọdagutan, ‘Wọ ti rẹ̀
p Ọmọ Rẹ kekere l’ẹkún:
Wò b’ o ti dubulẹ jẹ
Layọ̀ ninu ibojì Rẹ̀:
Kò s’ ami irora mọ,
T’ o nyọ ọkàn Rẹ̀ lẹnu.
- ‘Wọ kò mu pẹ́ titi mọ
L’ aiye ẹkun on òṣi yi;
Iwọ sì f’ ayọ̀ gbà a
Si ilẹ ọrun mimọ nì;
O wọṣọ àla mimọ,
O mba Ọ gbe n’ imọlẹ.
- L’ aipẹtiti, Oluwa
Mu wa de ‘bit’ ọmọ yi lọ;
Mu wa r’ ilẹ ayọ̀ na,
T’ o nf’ onjẹ ọrun bọ́ wọn:
p B’O ti gb’ ayò wa lọ yi,
‘Gbana ao tu jere rẹ̀. Amin.