- Awọn kékèké wo l’eyi
T’ nwọn tète l’ ajo aiye ja,
Ti nwọn sì de ‘bugbe ogo,
Eyiti nwọn ti nf’ oju si?
- “Emi t’òke Grinlandi wá.”
“Emi, lati ilẹ India.”
“Emi t’ ilẹ Afrika wá.”
“Emi, lat’ Erekùṣu nì.”
- Irin àjo wa ti kọja,
p Ẹkun ati irora tan;
A jumọ pade nikẹhìn,
Li ẹnu ibodè ọrun.
- A nreti lati gbọ pe, “Wá,”
Aṣẹgun ẹ̀ṣẹ on iku:
Gb’ori nyin soke, ilẹkun,
K’ awọn èro ewe wọlẹ. Amin.