- mf ‘Gbàti Samuẹl ji
T’ o gb’ ohùn Ẹlẹda
Ni gbolohun kọkan,
Ayọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ to !
Ibukun ni f’ ọmọ t’ o ri
Ọlọrun nitosi rẹ̀ bẹ.
- B’ Ọlọrun ba pè mi
Pe, ọ̀rẹ́ mi li On,
Ayọ mi y’o ti to !
Ngo si f’eti silẹ,
Ngo sá f’ ẹ̀ṣẹ̀ t’o kere jù,
B’ Ọlọrun sunmọ ‘tosí bẹ.
- Ko ha mba ni sọrọ̀?
Bẹni; n’nu Ọrọ Rẹ̀
O npè mi lati wá
Ọlọrun Samuẹl;
N’nu Iwe na ni mo ka pe
Ọlọrun Samuel npè mi.
- Mo lè f’ori pamọ
S’ abẹ itọju Rẹ,
Mo mọ̀ p’ Ọlọrun mbẹ
Lọdọ̀ mi n’gbagbogbo;
O ye k’ ẹrù ẹṣẹ bà mi,
‘Tor’ Ọlọrun sunmọ ‘tosi.
- Gbà mba nkà ọrọ Rẹ̀,
Ki nwi bi Samuẹl pe:--
Ma wi, Oluwa mi
Emi y’o gbọ Tirẹ;
‘Gba’ mo ba s wà n’ile Rẹ,
“Ma wi, ‘tori ‘ranṣẹ Rẹ ngbọ.” Amin.