Hymn 473: I love to hear the story which angel voices tell

Mo fe gbo itan kanna

  1. mf Mo fẹ gbọ itan kanna
    T’ awọn angẹli nsọ;
    di Bi Ọba Ogo ti wá
    Gbe aiye oṣi yi;
    p Bi mo tilẹ j’ẹlẹṣẹ,
    cr Mo mọ̀ eyi daju,
    f Pe Oluwa wa gbà mi,
    ‘Tori O fẹ mi bẹ.

  2. mf Mo yọ̀ pe Olugbala
    Ti jẹ ọmọde ri;
    Lati fi ọna mimọ
    Hàn awọn ọmọ Rẹ̀;
    Bi emi ba si tẹle
    Ipasẹ Rẹ̀ nihin,
    On kò ni gbagbe mi lai,
    ‘Tori O fẹ mi bẹ.

  3. f Ifẹ ati anu Rẹ̀,
    Y’o jẹ orin fun mi;
    B’emi kò tilẹ le ri,
    Mo mọ pe, O ngbọ mi:
    O si ti ṣe ileri,
    Pe, mo le lọ kọrin
    Larin awọn angẹli,
    ‘Tori O fẹ mi bẹ. Amin.