Hymn 472: Jehovah, the Lord of Glory

Jehofa! Olorun ogo

  1. mf Jehofa ! Ọlọrun ogo,
    Jẹ ki ọmọde yìn Ọ;
    p A wolẹ̀ n’ irẹlẹ̀ fun Ọ,
    Ore Rẹ ni orin wa.
    Ogun Seraf dapọ gberin
    Ifẹ Rẹ l’oke ọrun;
    Ọlọrun ogo, gbọ́ tiwa,
    B’ a ti nyin orukọ Rẹ.

  2. Emmanuel ! Iwọ t’a bi,
    p T’ a si fi kọ or’ igi,
    O pe ọmọde kekere,
    Lati wá si ọdọ Rẹ;
    Oluwa, ‘b’ o ti pè, a de,
    Jẹ k’ a ri anu Rẹ gbà !
    K’ awa, pel’ awọn ọmọ Rẹ,
    K’ a sin Ọ, k’ a si fẹ Ọ.

  3. A ba lè wà, k’ a si fẹ Ọ,
    K’ a si bẹ̀ru Rẹ l’ aiye;
    Nikẹhin, k’ a wà pẹlu Rẹ,
    f K a ri Ọ, k’ a si yìn Ọ.
    Jesu Ọlọrun itunu,
    Olori ọrẹ́ ! dide,
    f Fi igbala Rẹ bukun wa.
    Jọ tẹwọgba orin wa. Amin.