- mf Ọlọrun itẹ ogo Rẹ,
Yio wà titi lai;
Obi wa, talaka ni nwọn,
F’ibukun Rẹ fun wa.
- O wù Ọ ni, lati ṣe wa
p Ni talaka; ṣugbọn
Ma ṣe alabojuto wa,
‘Gba ti a wà l’aiye.
- A mọ̀, b’a tilẹ jẹ Tirẹ,
T’ a j’ orukọ mọ Ọ,
A j’ alejo; ṣugbọn ṣe wa
L’ ọmọ àṣayan Rẹ.
- Oluṣọ Agutan wa, wò
Agbo kekere Rẹ;
F’ọgọ at’ ọpa Rẹ tọ́ wa,
Ọmọ agb Tirẹ. Amin.