- mf Gbà Jesu wọ̀ tempili lọ,
Ohùn iyìn l’a gbọ;
Ọmọde jẹwọ ẹ̀tọ́ Rẹ̀,
f Gbogbo wọn si nyọ̀ si.
- ff Hosanna mu tempili ró,
Ahọn pipọ̀ dàlu:
Hosanna si Ọba t’ọrun,
S’ iru mimọ Dafid.
- Oluwa s’ ọjọ wa d’ọtun,
‘Gbat’ ọmọde yìn Ọ;
Agbara at’ ore Rẹ pọ̀
Bi t’ọjọ igbani. Amin.