mf “Ojo ibukun y’o si rọ̀!” Ileri ifẹ l’eyi; A o ni itura didun Lat’ ọdọ Olugbala. ff Ojo ibukun ! Ojo ibukun l’a nfe; Iri anu nsẹ̀ yi wa ká, ṣugbọn ojo l’ a ntọrọ.
f “Òjo ibukun y’o sì rọ̀!” Isọji iyebiye; Lori òke on pẹtẹlè Iró ọ̀pọ òjo mbọ̀. ff Òjo ibukun, &c.
f “Òjo ibukun y’o si rọ̀!” Rán wọn si wa Oluwa! Fun wa ni itura didùn Wá, f’ ọla fun ọ̀rọ Re. ff Ojo ibukun, &c.
f “Òjo ibukun y’o si rọ̀!” Iba jẹ le rọ̀ loni! B’ a ti njẹwọ f’ Ọlọrun wa T’ a npè orukọ Jesu. ff Ojo ibukun ! Ojo ibukun l’a nfe; Iri anu nsẹ̀ yi wa ká, ṣugbọn ojo l’ a ntọrọ. Amin.