Hymn 468: There's a Friend for little children

Ore kan mbe fun omode

  1. mf Ọrẹ kan mbẹ fun ọmọde
    Loke ọrun lọhun;
    Ọrẹ ti ki yipada,
    T’ ifẹ rẹ̀ kò le ku;
    p Kò dabi ọrẹ aiye,
    Ti mbajẹ lọdọdun;
    f Orukọ Rẹ̀ bi ọrẹ
    Wọ fun nigbagbogbo.

  2. mp Isimi kan mbẹ f’ọmọde
    Loke ọrun lọhun;
    F’awọn t’o f’ Olugbala,
    Ti nke “Abba Baba:”
    di Isimi lọwọ ‘yọnu;
    Lọw’ ẹ̀ṣẹ at’ ewu;
    p Nibit’ awọn ọmọde
    Y’o simi titi lai.

  3. mf Ile kan mbẹ fun ọmọde,
    Loke ọrun lọhun;
    f Nibiti Jesu njọba,
    Ile alafia !
    di Kò s’ile t’o jọ laiye
    T’a le fi ṣàkawé:
    f Ara rọ ‘lukulukù;
    Irọra na dopin.

  4. cr Ade kan mbẹ fun ọmọde
    Loke ọrun lọhun;
    Ẹnit’o ba nwò Jesu
    Y’o ri ade na de:
    Ade t’o logo julọ,
    Ti y’o fi fun gbogbo
    mf Awọn ọrẹ rẹ̀ laiye;
    Awọn t’o fẹ nihin.

  5. f Orin kan mbẹ fun ọmọde
    Loke ọrun lọhun;
    Orin ti kò le su ni,
    B’o ti wù k’a kọ to!
    mf Orin t’awọn angẹli
    Kò le ri kọ titi;
    Krist ki ṣ’Olugbala wọn,
    Ọba l’o jẹ fun wọn.

  6. f Ẹwu kan mbẹ fùn ọmọde
    Loke ọrun lọhun;
    Harpu olohùn didùn !
    Imọpẹ iṣẹgun !
    Gbogbo ẹ̀bun rere yi
    L’a ni ninu Jesu;
    p Ẹ wá, ẹnyin ọmọde,
    Ki nwọn le jẹ ti yin. Amin.