Hymn 467: Once in royal David's city

Nigba kan ni Betlehemu

  1. mf Nigba kan ni Bẹtlẹhẹmu,
    Ile kekere kan wà;
    Nib’ iya kan tẹ ‘mọ rẹ̀ si,
    Lori ibujẹ ẹran;
    Maria n’iya Ọmọ na,
    Jesu Krist si l’Ọmọ na.

  2. O t’ ọrun wá sode aiye,
    On l’ Ọlọrun Oluwa;
    O f’ile ẹran ṣe ile,
    ‘Bujẹ ẹran fun ‘bùsun.
    Lọdọ awọn òtoṣi
    Ni Jesu gbe li aiye.

  3. Ni gbogbo igba ewe Rẹ̀,
    O ngbọràn, o sì mb’ ọla,
    O nfẹràn o sì ntẹriba,
    Fun iya ti ntọju Rẹ̀:
    O yẹ ki gbogb’ ọmọde
    K’ o ṣe olugbọran bẹ.

  4. ‘Tori On jẹ awòṣe wa,
    A ma dagba bi awa,
    O kere, kò le da nkan ṣe,
    p A ma sọkun bi awa;
    O sì le ba wa darò,
    f O le ba wa yọ pẹlu.

  5. Ao fi’oju wa ri nikẹhìn
    Ni agbara ifẹ Rẹ̀,
    Nitori Ọmọ rere yi
    Ni Oluwa wa lọrun;
    O ntọ́ awa ọmọ Rẹ̀
    S’ ọna ibiti On lọ.

  6. Ki ṣe ni ibujẹ ẹran,
    Nibiti malu njẹun,
    L’ awa o ri; ṣugbọn lọrun,
    Lọwọ ọtun Ọlọrun,
    ‘Gbà ‘wọn ‘mọ Rẹ̀ b’ iràwọ
    Ba wà n’nu aṣọ àla. Amin.