- mf Mo fẹ ki ndabi Jesu,
Ninu ìwa pẹ̀lẹ́;
Kò s’ ẹnit’ o gbọrọ ‘binu
Lẹnu Rẹ̀ lẹ̀kan ri.
- Mo fẹ ki ndabi Jesu,
L’ adurà ‘gbagbogbo;
p Lori oke ni On nikan
Lọ pade Baba Rẹ̀.
- mf Mo fẹ ki ndabi Jesu,
Emi kò rì kà pe
Bi nwọn ti korira Rẹ̀ to,
O ṣ’ ẹnikan n’ ibi.
- Mo fẹ ki ndabi Jesu,
Ninu iṣẹ rere;
K’a le wi nipa temi pe,
“O ṣe ‘wọn t’o le ṣe.”
- Mo fẹ ki ndabi Jesu,
T’o f’iyọ́nu wipe,
“Jẹ k’ọmọde wa sọdọ Mi,”
Mo fẹ jẹ ipè Rẹ̀.
- p Ṣugbọn nkò dabi Jesu,
O si hàn gbangba bẹ;
cr Jesu fun mi l’ore-ọfẹ
Ṣe mi ki ndabi Rẹ. Amin.