- mf Jesu onirẹlẹ,
Ọmọ Ọlọrun:
Alanu, olufẹ,
p Gbọ́ ‘gbe ọmọ Rẹ.
- p Fi ẹ̀ṣẹ wa ji wa,
Si da wa n’ìde;
Fọ́ gbogbo oriṣa
Ti mbẹ l’ọkàn wa.
- f Fun wa ni omnira,
cr F’ifẹ s’ọkàn wa;
f Fà wa Jesu mimọ́,
S’ ibugbe l’oké.
- Tọ wa l’ọ̀na àjo,
Sì jẹ ọ̀na wa
La òkùn aiye já
S’ imọlẹ ọrun.
- Jesu onirẹlẹ,
Ọmọ Ọlọrun;
Alànu, Olufẹ,
Gbọ ‘gbe ọmọ Rẹ. Amin.