- mf Oluṣọ-agutan l’Olugbala wa,
B’ a ba wà l’aiya Rẹ̀, ki l’a o bẹ̀ru?
Sa jẹ k’a lọ s’ibi ti On ntọ́ wa si;
Iba jẹ aṣalẹ̀, tab’oko tutu.
- Oluṣọ-agutan, awa m’ohùn Rẹ,
p Wo b’ọ̀rọ kẹlẹ Rẹ̀ ti mmọkàn wa dùn.
B’o tilẹ̀ mba wa wi, jẹjẹ l’ohùn Rẹ̀,
Laisi Rẹ̀ lẹhin wa, awa o ṣegbé.
- p Oluṣọ-agutan kú f’agutan Rẹ̀.
cr O f’ẹjẹ Rẹ̀ wọ́n awọn agutan Rẹ̀;
O si fi ami Rẹ̀ s’ara wọn, O ni,
“Awọn t’o l’Ẹmi mi, awọn ni t’emi.”
- mf Oluṣọ-agutan, l’abẹ iṣọ́ Rẹ,
Bi korikò ba wá, ki y’o lè ṣe nkan.
p Bi awa tilẹ nrìn lojiji ikú,
Awa ki y’o bẹ̀ru, awa o ṣẹgun. Amin.