- mf Ọpọ íkán omi,
Yanrin kekeke;
cr Wọnyi l’o f’okun nla,
At’ ilẹ̀ẹaiye.
- mp Iṣẹju wa kọkan,
Ti a kò kàsi,
cr L’ o nd’ ọdun aimoye
Ti ainipẹkun.
- mp Iwa ore diẹ,
Ọrọ̀ ‘fẹ diẹ,
cr L’ o ns’ aiye di Eden,
Bi oke ọrun.
- p Iṣìṣe kekeke
L´o nmọkàn ṣìna,
Kuro l` ọ̀na rere,
Si ipa ẹ̀ṣẹ.
- mf Iṣẹ anu diẹ
T’a ṣe l’ọmọde,
cr Di ‘bukun f’orilẹ
T’o jina réré.
- f Awọn ewe l’ogo
Ngberin Angẹli;
di Ṣe wa yẹ Oluwa
p F’ẹgbẹ mimọ́ wọn. Amin.