- mf Bi ọ̀sùn gbẹ̀gẹ̀ eti ‘dò,
Tutu mini-mini;
B’ igbó dudu etì omi,
B’ itanna ipadò.
- Bẹ l’ ọmọ na yio dagba,
Ti nrìn l’ọna rere,
T’ọkàn rẹ̀ nfà si Ọlọrun,
Lat’ igbà ewe rẹ̀.
- di Ewé tutù l’ẹba odò,
p B’o pẹ̀, a rẹ̀ dànu;
Bẹ n’ itanna ipa omi
Si nrẹ̀ l’akoko rẹ̀.
- cr Ibukun ni fun ọmọ na,
Ti nrìn l’ọna Baba;
f Ọba ti ki pa ipò da,`,
Ẹni mimọ lailai.
- mf Oluwa, ‘Wọ l’a gbẹkẹle,
Fun wa l’ore-ọfẹ;
cr L’ ewe, l’agbà, ati n’iku,
Pa wa mọ b’ọmọ Rẹ. Amin.