- f Olorun ‘fe Isun anu,
Ore Rẹ ti pọ̀ to!
Oriṣi akoko t’o ndé
L’o nkédé ajò Rẹ.
- Nigbat’ àgbẹ gbìn ọ̀gbin rè,
T’o rì mọ ‘nu ilẹ,
Iwọ m’ akoko ti o nhù,
O sì rán òjo wà.
- f Tirẹ l’ agbara t’ojo ni,
T’o nmu ‘rugbin dàgba;
‘Wọ l’o nrán ‘mọlẹ orun wá,
p Ati ìri pẹlu.
- Akoko ‘rugbìn on ‘kore,
Iwọ l’o fi fun wa;
mf Má jẹ k’a gbagbe lati mọ́
Ibi ‘bùkún ti nwá.
- Isun ifẹ, ‘Wọ n’ iyìn wa;
Iwọ l’a nkọrin si,
Gbogbo ẹda l’ o sì dalu
N’nu iyìn didùn na. Amin.