Hymn 459: Now the day is over

Ojo oni lo tan

  1. mp Ọjọ oni lọ tan,
    Oru sunmọle:
    Okunkun ti de na,
    Ilẹ si ti ṣú.

  2. Okunkun bo ilẹ̀,
    Awọn ‘rawọ yọ;
    Ẹranko at’ẹiye,
    Lọ si bùsun wọn.

  3. mf Jesu f’orun didùn
    F’ ẹni alarẹ̀;
    p Jẹ ki ibukun Rẹ
    Pa oju mi de.

  4. Jẹ k’ ọmọ kekere
    La alá rere;
    Ṣ’ ọlọkọ̀ t’ewu nwu
    Ni oju omi.

  5. p Ma tọju alaisan
    Ti kò r’orun sùn;
    mf Awọn ti nro ibi,
    Jọ da wọn l’ẹkun.

  6. p Ninu gbogbo oru,
    Jẹ k’ angẹli Rẹ
    Ma ṣe oluṣọ mi,
    L’ori ẹni mi.

  7. cr Gbat’ ilẹ̀ ba si mọ́,
    Jẹ k’ emi dide;
    f B’ ọmọ ti kò l’ ẹ̀ṣẹ
    Ni iwaju Rẹ.

  8. ff Ogo ni fun Baba,
    Ati fun Ọmọ,
    Ati f’ Ẹmi Mimọ́,
    Lai ati lailai. Amin.