- mp Jesu, ‘Wọ onirẹlẹ̀,
Wò mi, emi ọmọe;
Kanu fun aimọkan mi,
Si jẹ k’ emi wadọ̀ Rẹ.
- cr Mo fẹ lati wadọ Rẹ,
Oluwa mi, maṣe kọ̀;
Oluwa, fun mi n’ipo,
Ninu ‘jọba ore Rẹ.
- mf Ọdagutan Ọlọrun,
‘Wọ ni k’o j’ apẹrẹ mi;
di Iwọ tutù, ‘Wọ tẹnu;
p O si ti s’ ọmọde ri.
- Jesu, Ọrẹ ọmọde,
Ni ọwọ Rẹ ni mo wà;
cr Ṣe mi gẹgẹ b’O ti ri,
Sì ma gbe ‘nu mi titi. Amin.