Hymn 457: Come, Holy Spirit, come;

Wa, Emi Mimo, wa

  1. mp Wá, Ẹmi Mimọ́, wá,
    Gb’ ẹ̀bẹ ìrẹlẹ mi;
    Fi ọkàn mi ṣe ile Rẹ,
    F’ ibukun Rẹ sibẹ̀.

  2. cr F’ ifẹ Rẹ, s’ ọkàn mi,
    K’o si mu k’ o ma jẹ́
    Ọkàn mimọ́, ọkàn ayọ̀,
    Ati ibugbe Rẹ.

  3. mf Ni igba ewe mi,
    Ki ore-ọfẹ Rẹ
    Mu ọpọ eso rere wá,
    Fun ‘yin Orukọ Rẹ. Amin.