Hymn 456: Jesus, Father of the Child

Jesu, Baba omode

  1. f Jesu, Baba ọmọde,
    Aṣẹ Rẹ ni awa nṣe:
    A m’ọmọ yi wa ‘dọ Rẹ,
    Ki iwọ sọ di Tirẹ.

  2. Ninu ẹṣẹ ni a bi,
    Wẹ kuro nin’ẹṣẹ rẹ̀;
    p Ẹjẹ Rẹ ni a fi ra,
    f K’o pin ninu Ẹbun Rẹ. Amin.