- f Baba, Apat’ agbara wa,
Ileri ẹniti kì ‘yẹ̀,
Sinu agbo enia Rẹ,
Jọ, gbà ọmọ yi titi lai.
- mp A ti f’omi yi sami fun,
Li Orukọ Mẹtalọkan;
cr A si ntọrọ ipò kan fun,
larin awọn ọmọ Tirẹ.
- mf A sa l‘ami agbelebu,
Apẹrẹ ìya ti O jẹ;
Krist, k’ ileri rẹ̀ owurọ
Jẹ́ ‘jẹwọ ọjọ aiye rẹ̀.
- cr Fifunni, k’iku on ìye,
Má yà ọmọ Rẹ lọdọ Rẹ;
f K’on jẹ ọm’-ogun Rẹ totọ,
Ọm’ọdọ Rẹ, Tirẹ laila. Amin.