- mf Jesu a gb’ ọkàn wa si Ọ,
Mi Ẹmi Rẹ si wọn;
Si baptis’ ọmọde wọnyi,
Baptis’ wọn s’ikú Rẹ.
- K’ ororo Rẹ wà l’ori wọn (rẹ̀),
Si tun ẹmi (rẹ̀) wọn ṣe:
Kọ orukọ Rẹ Oluwa,
Si aiya gbogbo wọn.
- Ki nwọn (on) jẹ iranṣẹ Tirẹ,
K’ otọ ṣ’ àmure wọn (rẹ̀):
Ki nwọn (on) ṣ’olupin ikú Rẹ.
At’ ọmọ lẹhìn Rẹ.
- Gbin gbogbo wa si ikú Rẹ,
K’a lè ni iyè Rẹ;
K’a lè gbe agbelebu Rẹ.
K’a lè ni ade Rẹ. Amin.