Hymn 450: Jesus, Thou that feedeth Thy flock

Jesu, ’Wo ti mbo agbo Re

  1. mf Jesu, ‘Wọ ti mbọ́ agbo Rẹ,
    B’oluṣ’agutan rere,
    Ti ‘ṣikẹ awọn t’o dera,
    Ti ‘gb’ awọn ọdọ́ mọra.

  2. mp Jọwọ! Gbà ọmọde wọnyi,
    F’ anu gbá wọn mọ aiya;
    Gbangba l’o daniloju pe,
    Ewu ki y’o wu wọn n’bẹ̀.

  3. Nibẹ, nwọn kò ni ṣako mọ,
    Ẹkun ki y’o lè pa wọn;
    Jẹ ki ‘rọ̀nú ifẹ nla Rẹ
    Dabò wọn l’ ọna aiye.

  4. N’nu pápá Rẹ oke ọrun,
    Jẹ ki nwọn ri ‘bi ‘simi,
    Ki nwọn j’oko tutu yọ̀yọ̀,
    Ki nwọn m’mi ifẹ Rẹ. Amin.