f Wá, ẹnyin ọlọpe, wá, Gbe orin ikore ga; Irè gbogbo ti wọle K’ otutu ọyẹ to de; mf Ọlọrun Ẹlẹda wa L’o ti pèse f’ aini wa; ff Wa k’a re ‘le Ọlọrun Gbe orin ikore ga.
mf Oko Ọlọrun l‘ aiye, Lati s’ eso iyìn Re; Alikama at’èpo Ndagba t’ arò tab’ ayọ̀: cr Ehu na, ìpẹ́ tele, Ṣiri ọka nikẹhin; p Oluwa ‘kore, mu wa Jẹ eso rere fun Ọ.
mf N’tori Ọlọrun wa mbọ̀. Y’o si kore Rẹ̀ sile; On o gbọ̀m gbogbo pànti Kuró l’oko Rẹ̀ n’jọ na: p Y’o t’ aṣẹ f’awọn Angẹl’ Lati gbá èpo s’iná, f Lati kó alikama Si abà Rẹ̀ titi lai.
f Bẹni, ma wá, Oluwa Si ikore ikẹhìn; Ko awọn enia Rẹ jọ Kuro l’ẹṣẹ at’ arò: cr Sọ wọn di mimọ lailai Ki nwọn le mà ba Ọ gbe: ff Wà t’ Iwọ t’ Angẹli Re Gbe orin ikore ga. Amin.