- Balogun ! Olugbala wa,
Gb’ ọmọ wọnyi t’a bùn Ọ;
Ṣe wọn yẹ fun iṣẹ Tirẹ,
Arole ìye wọnyi.
- Arẹwà Baba wa ọrun,
Mu k’ awọn wọnyi jọ Ọ
N’nu awòran Tirẹ papa,
Lọ́ wọn s’ agbala oke.
- Ṣe wọn l’ agánnigàn mimọ,
Ọmọ-ogun t’o lera;
Ki nwọn fọ itẹgun Eṣu,
Ki nwọn sì ṣẹgun aiye.
- K’ ọrọ Rẹ dabi òguna,
L’ ẹnu awọn ọmọ Rẹ;
Ti y’o jo ẹṣẹ l’ ajorun,
K’ara ba lè da ṣáṣá
- Pa wọn mọ fun ‘ṣẹ ogo Rẹ,
Ki nwọn wà lailabawọn;
Kọ́ wọn lati r’ agbelebu,
Lojojumọ aiye wọn.
- Bukun ‘lanà igbala yi,
Fun ire ọmọ wọnyi;
Gbà wọn, tọ́ wọn, sì ma ṣọ wọn,
Nikẹhin gb’ọkàn wọn là. Amin.