- mf Nihinyi n’ isimi gbe wà
Niha rẹ t’ ẹjẹ nṣàn;
Eyi nikan n’ ireti mi,
p Pe Jesu kú fun mi.
- Olugbala, Ọlọrun mi,
Orisun f’ ẹ̀ṣẹ mi;
Ma f’ ẹjẹ Rẹ wọ́n mi titi,
K’ emi lè di mimọ́.
- mp Wẹ̀ mi, si ṣe mi ni Tirẹ,
Wẹ̀ mi, si jẹ temi;
Wẹ mi, k’ iṣ’ ẹsẹ̀ mi nikan,
Ọwọ at’ ọkàn mi.
- f Ma ṣiṣẹ l’ọkàn mi, Jesu,
Titi ‘gbagbọ y’o pin;
Tit’ ireti y’o fi dopin,
T’ ọkàn mi y’o simi. Amin.