Hymn 446: This is Jehovah’s great command

Eyi l’ ase nla Jehofa

  1. f Eyi l’ aṣẹ nla Jehofa,
    Yio wà titi lai;
    Ẹlẹṣẹ b’ iwọ at’ emi,
    K’ a tun gbogbo wa bi.

  2. p Okunkun y’o jẹ ipa wa,
    B’ a wà ninu ẹ̀ṣẹ;
    A ki o rì ijọba Rẹ̀,
    Bi a kò d’ atunbi.

  3. Bi baptisi wa jẹ ‘gbarun,
    Asan ni gbogbo rẹ;
    Eyi kò lè w’ẹ̀ṣẹ wa nù,
    Bi a kò tun wa bi.

  4. Wò iṣẹ wère ti à nṣe,
    Kò ni iranwọ Rẹ̀;
    Nwọn kò s’ ọkàn wa di ọtun,
    B’ awa kò d’ atunbi.

  5. f Lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ
    cr Ja ẹ̀wọn Eṣu nù;
    f Gbà Kristi gbọ́ tọkàntọkàn
    ff Iwọ o d’ atunbi. Amin.