- f Jesu, Iwọ l’a gbohùn si,
Mí Ẹmi Mimọ́ Rẹ
Si awọn enia wọnyi;
p Baptis wọn s’ iku Rẹ.
- f K’ o fi agbara Rẹ fun wọn,
cr Fun wọn l’ọkàn titun!
Kọ ‘rukọ Rẹ si aiyà wọn,
Fi ẹmi Rẹ kùn wọn.
- f Jẹ ki nwọn jà bi ajagun
Labẹ ọpagun Rẹ,
Mù wọn f’ otitọ d’ àmure,
Ki nwọn rìn l’ ọ̀na Rẹ.
- mf Oluwa, gbìn wa s’ iku Rẹ.
K’a jogun ìye Rẹ;
f Laiye k’a rù agbelebu,
cr K’ a ni ade ọrun. Amin.