- mp Sunmọhìn, k’o gbà Ara Oluwa,
K’o mu Ẹjẹ mimọ t’a ta fun ọ.
- Ara at’ ẹjẹ na l’o gbà ọ là,
cr N’ itura ọkan, f’ ọpẹ f’Ọlọrun.
- f Ẹlẹbùn ìgbala, ỌmọBaba,
Agbelebu Rẹ̀ fun wa n’ iṣẹgun.
- di A fi On rubọ fun tàgba tewe.
On tikarẹ̀ l’ Ẹbọ, On l’ Alufa.
- mf Gbogb` ẹbọ awọn Ju laiye ‘gbanì
J’ apẹrẹ ti nsọ t’ Ẹbọ ‘yanu yi.
- On l’ Oludande, On ni Imọlẹ,
O nf’ Ẹmi ràn awọn Tirẹ̀ lọwọ.
- mp Njẹ, ẹ f’ọkàn igbagbọ sunmọ ‘hin,
ki ẹ sì gbà ẹ̀ri ìgbala yi.
- mf On l’o nṣakoso enia Rẹ̀ laiye,
On l’o nf’ ìye ainipẹkun fun wa
- f O nf’ onjẹ ọrun f’ awọn t’ ebi npa,
Omi ìye fun ọkàn npongbẹ.
- p Onidajọ wa, Olugbala wa,
Pẹlu wa ni àse ifẹ Rẹ yi. Amin.