- mf Oluwa, mo mba Ọ pade nihin,
Igbagbọ mu mi wo ohun ọrun;
Ngo fi agbara rọ̀ mọ ore Rẹ,
p Ngo si fi ara arẹ mi tì Ọ.
- mf Emi ‘o jẹ akara Ọlọrun,
Emi o mu wain ọrun pẹlu Rẹ;
Nihin, ngo sọ ẹrù aiye kalẹ̀,
Nihin, ngo gba idariji ẹṣẹ.
- Emi kò ni ‘ranwọ mi lẹhin Rẹ,
Apa Rẹ l’o to lati f’ara ti;
cr O to wayi, Oluwa mi, o to,
Agba mi mbẹ ninu ipa Rẹ.
- p.cr Temi ni ẹṣẹ, Tirẹ l’ododo,
p.cr Temi l’ẹbi, Tirẹ l’ẹjẹ ‘wẹnu;
mf Ẹwù, abò, on alafia mi
L’Ẹjẹ at’ ododo Rẹ, Oluwa.
- Gbat’ a ba dide t’ a si palẹmọ,
T’a ko akara ati waini kuro;
Sibẹ Iwọ wà nihin, Oluwa,
Lati jẹ Orùn ati Asa mi.
- di Bi àse yi ti nde ti o si nlọ,
cr O nran wa leti àse nla tọrun;
f O nfi ayọ didun àse na han,
Ase ayọ yawo Ọd’-Agutan. Amin.