Hymn 441: Lord, to whom except to Thee

Tal’ awa ba ha to lo

  1. mf Tal’ awa ba ha tọ̀ lọ,
    Bikoṣ’ ọdọ Rẹ Jesu?
    ‘Wọ ti ṣe imọlẹ wa,
    At’ iye ainipẹkun.
    mp Ẹmi Rẹ ti l’ọ̀wọ to,
    T’ Ẹmi Mimọ́ nmí si wa?
    Onjẹ Rẹ atọrunwa
    Li ọkàn atunbi nfẹ.

  2. mf Israeli l’atijọ,
    Nwọn jẹ manna, nwọn si kú;
    Awọn t’o jẹ l’ara Rẹ,
    Nwọn kì y’o kebi lailai.
    mp Tal’ awa ba ha tọ̀ lọ,
    ‘Gbat’ ibi ba yi wa ka?
    cr Bikoṣ’ ọdọ Rẹ Jesu,
    Wọ t’ iṣe iranwọ wa.

  3. mf Tal’ o lé wẹ̀ ọkàn wa,
    T’o si lè gbọ́ igbe wa?
    Tani lè kún ọkàn wa,
    Olugbala, lẹhin Rẹ?
    f Iyìn at’ ọpẹ ni fun Ọ
    Titi, ‘Wọ Ọlọrun mi;
    Ninu Rẹ l’ em’ o ma wà,
    Ma wà ninu mi titi. Amin.