- mf ‘Wọ Ọba anu, lat’ or’ itẹ Rẹ,
Fi ifẹ wò wa, si gbọ igbe wa.
- mp ‘Wọ Olusagutan enia Rẹ,
Pa awọn agbo agutan Rẹ mọ.
- p Olugbala, iku Rẹ n’ìye wa,
F’ìye ainipẹkun fun gbogbo wa.
- cr Onjẹ ọrun, Iwọ ni onje wa,
Ṣe ‘ranwọ ọkàn wa nigba ‘pọnju.
p ‘Wọ l’Alabarò, Ọrẹ ẹlẹṣẹ,
cr ‘Wọ n’Ibu ayọ̀ wa titi lailai.
- f Wa f’ore-ọfẹ Rẹ mu ‘nu wa dùn,
Si jẹ k’a ma ri ojurere Rẹ.
- mf Nigba ọsan, ati nigba oru,
Sunmo wa, k’o s’okùn wa d’imọlẹ.
- cr Ma ba wa lọ, k’o sì ma ba wa gbe,
N’iyè, n’iku, ma jẹ itunu wa.
- mf L’ojojumọ f’oju ‘fẹ Rẹ tọ́ wa,
Si mu wa e ‘le wa l’alafia. Amin.