f A f’ọpẹ f’ Ọlọrun, L’ọkàn ati ohùn wa, Ẹni ṣ’ohun ‘yanu, N’nu Ẹnit’ araiye nyọ̀: mp Gbat’ a wà l’ọm’ọwọ On na l’o ntọju wa O si nf’ẹ̀bun ifẹ Ṣe ‘tọju wa sibẹ̀.
mf Ọba Onib’ọrẹ Mà fi wa silẹ lailai Ayọ ti kò lopin On ‘bukun y’o jẹ tiwa; Pa wa mọ n’nu ore, Tọ wa gb’ a ba damu, Yọ wa ninu ibi Laiye ati l’ọrun.
un ff K’a f’ iyin on ọpẹ F’ Ọlọrun Baba, Ọmọ, Ati Emi Mimọ; Ti o ga julọ l’ọrun, Ọlọrun kan lailai, T’aiye at’ọrun mbọ, Bẹ l’o wà d’isiyi, Bẹni y’o wà lailai. Amin