- mf Ase ifẹ ọrun,
Ore-ọfẹ l’o jẹ
K’a jẹ akara, k’a mu wain,
Ni ‘ranti Rẹ Jesu.
- Oluwa, a nduro,
Lati kọ́ ẹkọ na;
T’ohun ti mbẹ l’aiya Baba,
At’ ore-ọfẹ Rẹ.
- cr Ẹri-ọkàn ko to,
Igbagbọ l’o fi hàn;
Pe, adun akara ìye,
Ẹkún ifẹ Rẹ ni.
- Ẹjẹ ti nṣàn f’ẹṣẹ,
L’a r’apẹrẹ rẹ̀ yi;
Ẹrí si ni li ọkàn wa,
Pe Iwọ fẹran wa.
- mf A ! ẹrí diẹ yi,
Bi o ba dùn bayi;
cr Y’o ti dùn to l’oke ọrun,
Gbat’ a ba r’oju Rẹ?
- f Lati ri oju Rẹ,
Lati ri b’O ti ri,
K’a si ma sọ ti ore Rẹ
Titi aiyeraiye. Amin.