f Kil’o lẹ w’ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, Kò si, lẹhin ẹ̀jẹ̀ Jesu; Ki l’o tun lè wò mi sàn, Kò si, lẹhin ẹ̀jẹ́ Jesu. mp A ! ẹ̀jẹ̀ yebiye, T’o mu mi fún bi sno, Kò s’isun miràn mọ, Kò si, lẹhin ẹ̀jẹ̀ Jesu.
Fun ‘wẹ̀nùmọ mi, nkò ri Nkan mi, lẹhin ẹ̀jẹ̀ Jesu; Ohun ti mo gbẹkẹle Fun ‘dariji, l’ẹ̀jẹ̀ Jesu. A ! ẹ̀jẹ̀ yebiye, &c.
Etùtu f’ẹ̀ṣẹ̀ kò si, Kò si, lẹhin ẹ̀jẹ̀ Jesu; Iṣẹ rere kan kò si, Kò si, lẹhin ẹ̀jẹ̀ Jesu. A ! ẹ̀jẹ̀ yebiye, &c.
Gbogbo igbẹkẹle mi, Ireti mi, l’ẹ̀jẹ̀ Jesu; Gbogbo ododo mi ni Ẹjẹ̀, kìkì ẹ̀jẹ̀ Jesu. mf A ! ẹ̀jẹ̀ yebiye, &c. Amin.